Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àkànṣe Ìwàásù Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣù September

Àkànṣe Ìwàásù Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣù September

Lóṣù September, a máa sapá gan-an láti fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn. Àwọn akéde tó bá gba aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè pinnu láti ròyìn ọgbọ̀n (30) wákàtí. Báwo la ṣe máa ṣe àkànṣe ìwàásù yìí?

  • Nígbà Àkọ́kọ́: Fi ohun tó wà ní ẹ̀yìn ìwé náà han ẹni náà, kó o sì jẹ́ kó mọ bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn títí kan àwọn tó o ti bá sọ̀rọ̀ nígbà kan rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè má tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn báyìí àti ìwé tá à ń lò lè mú kó wù wọ́n. Ẹ má ṣe fi ìwé náà sílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà àwọ́n tẹ́ ò bá bá nílé, ẹ má sì fi ránṣẹ́ sáwọn tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ lè pinnu láti fi kún iye ìgbà tẹ́ ẹ máa ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù lóṣù yẹn.

  • Àwọn Ipò Míì: Tó bá jẹ́ pé ìjọ yín máa ń lo àtẹ ìwé, ẹ kó ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì síbẹ̀. Jẹ́ kí àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìwé náà mọ̀ pé a máa ń lò ó láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. O lè fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn wọ́n níbẹ̀ tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣètò ìgbà míì tó máa rọ ẹni náà lọ́rùn. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn lè ṣètò pé káwọn akéde tó nírìírí lọ wàásù láwọn ilé ìtajà tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí wọ́n bá rí. O tún lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tó o wàásù fún lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.

Jésù pàṣẹ fún wa pé ká máa ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ká sì máa kọ́ wọn.’ (Mt 28:19, 20) Àdúrà wa ni pé kí àkànṣe ìwàásù yìí ràn wá lọ́wọ́ láti pa àṣe Jésù mọ́.