ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Òpó Méjì
Wọ́n kọ́ àwọn òpó ràgàjì méjì sí ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà (1Ọb 7:15, 16; w13 12/1 13 ¶3)
Wọ́n fún àwọn òpó náà ní orúkọ tó nítumọ̀ (1Ọb 7:21; it-1 348)
Táwọn èèyàn náà bá gbára lé Jèhófà, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “fìdí [tẹ́ńpìlì náà] múlẹ̀ gbọn-in” (1Ọb 7:21, àlàyé ìsàlẹ̀; Sm 127:1)
Jèhófà lè ti ràn wá lọ́wọ́ láti borí ọ̀pọ̀ ìṣòro ká lè wá sínú òtítọ́. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa gbára lé e nìṣó tá a bá fẹ́ “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—1Kọ 16:13.
BI ARA Ẹ PÉ, ‘Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé mo gbára lé Jèhófà?’