MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ètò Ọlọ́run ń ṣe láti ṣètò àwọn ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ, ọ̀pọ̀ akéde sì ti rí i pé àwọn àbá yẹn gbéṣẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Àmọ́, bí nǹkan ṣe rí lágbègbè kan yàtọ̀ sí òmíì, torí náà àwọn akéde lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalè míì tàbí kí wọ́n jíròrò àkòrí míì táwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa tẹ̀ lé ìtọ́ni èyíkéyìí tí wọ́n bá fún wa nígbà àkànṣe ìwàásù. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa ní bá a ṣe máa pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Mt 24:14.
Kí àwọn akéde tó bá níṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ jíròrò àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Àmọ́ wọ́n lè lo ìbéèrè míì, ẹsẹ Bíbélì míì tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó máa gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, àyàfi tí ìtọ́ni bá sọ pé kí wọ́n lo èyí tó wà nínú ìwé ìpàdé. Ìtọ́ni yìí là á máa tẹ̀ lé dípò èyí tó wà ní ojú ìwé 8 nínú ìwé ìpàdé June 2020.