MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI | OHUN TÓ O LÈ FI ṢE ÀFOJÚSÙN NÍ ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN TÓ Ń BỌ̀
Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà
Tá a bá pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ìyẹn á fi hàn pé à ń lo okun wa lọ́nà tó dáa. (1Kọ 9:26) Torí pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ kógbá sílé, àwọn àfojúsùn tá a bá ní máa jẹ́ ká lè fọgbọ́n lo àkókò wa. (Ef 5:15, 16) Nínú ìjọsìn ìdílé yín, á dáa kẹ́ ẹ jíròrò àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè fi ṣe àfojúsùn yín lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ yìí. Nínú ìwé ìpàdé yìí, ẹ máa rí onírúurú àbá nípa àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè fi ṣe àfojúsùn yín. Á dáa kẹ́ ẹ ronú lé wọn lórí, kẹ́ ẹ sì gbàdúrà nípa ẹ̀.—Jem 1:5.
Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹ lè ran ó kéré tán ẹnì kan lọ́wọ́ nínú ìdílé yín láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní lè dójú ìlà wákàtí tá à ń béèrè, o lè fọ̀rọ̀ náà lọ aṣáájú-ọ̀nà kan tí ipò yín jọra. (Owe 15:22) Kódà, ẹ lè pe aṣáájú-ọ̀nà kan wá sí ìjọsìn ìdílé yín, kẹ́ ẹ sì fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Lẹ́yìn náà, kọ onírúurú ọ̀nà tó o lè gbà ṣètò àkókò ẹ. Tó bá jẹ́ pé o ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà nígbà kan rí, wò ó bóyá ipò tó o wà báyìí lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà pa dà.
Ṣé àwọn kan nínú ìdílé yín lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ? Tó bá jẹ́ pé o ò fi bẹ́ẹ̀ lókun, o ṣì lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó o bá ń lo àkókò díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lójoojúmọ́. Tó bá jẹ́ pé o kì í ráyè jáde láàárín ọ̀sẹ̀ torí iṣẹ́ tàbí torí pé o jẹ́ ọmọléèwé, o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láwọn oṣù tẹ́ ẹ bá ní ọlidé tàbí oṣù tó ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún. Sàmì sí oṣù tó o pinnu láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sórí kàlẹ́ńdà kan, kó o sì kọ bó o ṣe máa ṣètò àkókò ẹ kó o lè dójú ìlà wákàtí tá a béèrè.—Owe 21:5.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ JẸ́ ONÍGBOYÀ . . . Ẹ̀YIN AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ni àpẹẹrẹ Arábìnrin Aamand kọ́ wa nípa bí Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó àwọn tó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà?