Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

O Lè Mú Kí Ayọ̀ Túbọ̀ Wà Nínú Ìdílé Rẹ

O Lè Mú Kí Ayọ̀ Túbọ̀ Wà Nínú Ìdílé Rẹ

Jèhófà fẹ́ kí àwọn tó wà nínú ìdílé láyọ̀. (Sm 127:3-5; Onw 9:9; 11:9) Àmọ́, kòókòó jàn-án-jàn-án ìgbésí ayé lè mú káwọn tó wà nínú ìdílé má ráyè ara wọn, kíyẹn sì fa ìṣòro nínú ìdílé. Bákan náà, tí ẹnì kan nínú ìdílé bá ṣàṣìṣe tàbí tó ṣe ohun tó dùn wá, a lè má láyọ̀ mọ́. Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé lè ṣe kí ayọ̀ lè túbọ̀ wà nínú ìdílé wa?

Ọkọ gbọ́dọ̀ máa bọlá fún ìyàwó rẹ̀ tàbí lédè míì kó máa pọ́n ọn lé. (1Pe 3:7) Ó yẹ kó máa wáyè fún un, kó má sì retí pé kó ṣe ohun tó ju agbára ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kó máa jẹ́ kíyàwó ẹ̀ mọ̀ pé òun mọrírì gbogbo ohun tó ń ṣe nínú ilé. (Kol 3:15) Ó tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá jẹ́ kó mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó sì máa gbóríyìn fún un.​—Owe 31:28, 31.

Ó yẹ kí ìyàwó náà máa ti ọkọ ẹ̀ lẹ́yìn. (Owe 31:12) Bákan náà, ó gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún un, kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀. (Kol 3:18) Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí ìyàwó máa bá ọkọ ẹ̀ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kó sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ dáadáa lójú àwọn míì.​—Owe 31:26.

Ó yẹ káwọn òbí náà máa wáyè fáwọn ọmọ wọn. (Di 6:6, 7) Kí wọ́n máa sọ fáwọn ọmọ wọn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn. (Mt 3:17) Kódà, tó bá gba pé kí wọ́n bá wọn wí, ó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́, kí wọ́n sì máa ń gba tiwọn rò.​—Ef 6:4.

Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa bọlá fáwọn òbí wọn, kí wọ́n sì máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. (Owe 23:22) Ó tún yẹ kí wọ́n máa sọ ohun tí wọ́n ń rò àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn fáwọn òbí wọn. Bákan náà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa gba ìbáwí táwọn òbí wọn bá fún wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn.​—Owe 19:20.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ AYỌ̀ WÀ NÍNÚ ÌDÍLÉ RẸ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìdílé náà ṣe kí ayọ̀ lè wà nínú ìdílé wọn?