Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àkànṣe Ìwàásù Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run Lóṣù September

Àkànṣe Ìwàásù Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run Lóṣù September

Lóṣù September, a máa ṣe ìkéde àkànṣe kan láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè yanjú ìṣòro aráyé. (Mt 24:14) Báwo nìwọ náà ṣe lè kópa nínú ẹ̀? O lè ka ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Tẹ́ni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, fún un ní Ilé Ìṣọ́ No. 2 2020. Rí i pé o tètè pa dà sọ́dọ̀ ẹni náà, kó o sì fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!​—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù September lè pinnu bóyá wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tàbí ọgbọ̀n (30) wákàtí làwọn máa ròyìn.

Láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ìjọba tó ń ta kò ó. (Da 2:44; 1Kọ 15:24, 25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu àkànṣe ìwàásù yìí ká lè fi hàn pé ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà, Ìjọba rẹ̀ la sì fara mọ́.