Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀?

Àwọn Nǹkan Wo Lo Lè Fi Ṣe Àfojúsùn ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀?

Àfojúsùn tẹ̀mí ni ohunkóhun tá a bá ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ torí ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tàbí ká lè múnú Jèhófà dùn. Àwọn àfojúsùn yìí máa ń jẹ́ ká túbọ̀ tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa. Tá a bá sì yááfì àkókò àti okun wa kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ wọ́n, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. (1Ti 4:15) Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa ronú lórí àwọn ohun tá a fi ṣe àfojúsùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ipò wa máa ń yí pa dà. Ohun tá a fi ṣe àfojúsùn nígbà kan lè má bá ipò wa mu mọ́ tàbí kọ́wọ́ wa ti tẹ̀ ẹ́, ìyẹn lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun míì tá a máa fi ṣe àfojúsùn.

Àsìkò tó dáa téèyàn lè ronú nípa ẹ̀ ni kí ọdún iṣẹ́ ìsìn tó bẹ̀rẹ̀. Ẹ ò ṣe jíròrò ohun tẹ́ ẹ lè ṣe nígbà ìjọsìn ìdílé yín, kẹ́ ẹ sì ronú nípa ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè ṣe àti ohun tẹ́ ẹ lè ṣe lápapọ̀ bí ìdílé?

Àwọn nǹkan pàtó wo lo máa fẹ́ ṣe tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí, kí lo sì lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ wọ́n?

Bíbélì kíkà, ìdákẹ́kọ̀ọ́, lílọ sípàdé, dídáhùn nípàdé.​—w02 6/15 15 ¶14-15

Iṣẹ́ ìwàásù.​—w23.05 27 ¶4-5

Àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni.​—w22.04 23 ¶5-6

Àwọn nǹkan míì: