MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Fìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Bíi Ti Jèhófà
Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sẹ́nì kan. (Sm 103:11) Ìfẹ́ yìí kì í ṣe ìmọ̀lára kan lásán tó kàn wà fún ìgbà díẹ̀; àwọn tó bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ síra wọn máa ń sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, ìfẹ́ yẹn máa ń jinlẹ̀ gan-an, ó sì máa ń wà pẹ́ títí. Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà fi ìfẹ́ yìí hàn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó ń fi wọ́n ṣẹrú, ó sì mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Sm 105:42-44) Ó máa ń jà fáwọn èèyàn rẹ̀, léraléra ló sì máa ń dárí jì wọ́n tí wọ́n bá ṣẹ̀. (Sm 107:19, 20) Bá a ṣe ń “fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,” ó máa ń wù wá láti fara wé e.—Sm 107:43.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “FARA BALẸ̀ KÍYÈ SÍ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ ṢE NÍTORÍ ÌFẸ́ RẸ̀ TÍ KÌ Í YẸ̀,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn?
-
Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yááfì àwọn nǹkan kan tá a bá fẹ́ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn?