ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Nehemáyà Fi Ara Ẹ̀ Jìn Dípò Kó Jẹ Gàba
Nehemáyà kò fi ipò ẹ̀ wá àǹfààní ara ẹ̀ (Ne 5:14, 15, 17, 18; w02 11/1 27 ¶3)
Nehemáyà ò káwọ́ gbera, kó sì máa pàṣẹ fáwọn èèyàn náà; dípò bẹ́ẹ̀ òun fúnra ẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà (Ne 5:16; w16.09 6 ¶16)
Nehemáyà bẹ Jèhófà pé kó rántí gbogbo ohun tí òun ṣe fáwọn èèyàn náà (Ne 5:19; w00 2/1 32)
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gómìnà ni Nehemáyà, kò retí pé káwọn èèyàn máa gbé òun gẹ̀gẹ̀. Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fún gbogbo àwọn tó ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ohun tí mo lè ṣe fáwọn míì ló máa ń gbà mí lọ́kàn, àbí ohun táwọn míì lè ṣe fún mi?’