Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nítorí Wa

Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nítorí Wa

Àwọn alábòójútó àyíká àtìyàwó wọn máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì máa ń fi ara wọn jìn fáwọn ará. Torí pé ẹlẹ́ran ara bíi tiwa làwọn náà, ó máa ń rẹ̀ wọ́n nígbà míì. Àwọn ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń ṣàníyàn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì. (Jem 5:17) Láì fìyẹn pè, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń ronú nípa bí wọ́n ṣe lè gba àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin láwọn ìjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò níyànjú. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó yẹ ká máa fún àwọn alábòójútó àyíká ní “ọlá ìlọ́po méjì.”​—1Ti 5:17.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ ṣèbẹ̀wò sáwọn ará ní Róòmù kó lè “fún [wọn] ní ẹ̀bùn ẹ̀mí,” inú ẹ̀ dùn torí ó mọ̀ pé àwọn jọ máa “fún ara [àwọn] ní ìṣírí.” (Ro 1:11, 12) Ṣé o mọ̀ pé ìwọ náà lè fún alábòójútó àyíká àtìyàwó ẹ̀ níṣìírí, ìyẹn tó bá níyàwó? Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÉSÍ AYÉ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ TÓ LỌ SÌN NÍ ÌGBÈRÍKO KAN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ọ̀nà wo làwọn alábòójútó àyíká àtìyàwó wọn máa ń gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ará níjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò?

  • Ọ̀nà wo ni ìbẹ̀wò wọn ti gbà ṣe ẹ́ láǹfààní?

  • Kí la lè ṣe láti fún wọn níṣìírí?