Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ́sírà Fi Ìwà Rẹ̀ Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

Ẹ́sírà Fi Ìwà Rẹ̀ Gbé Orúkọ Jèhófà Ga

Ẹ́sírà jẹ́ kí ohun tó kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì hàn nínú ìwà rẹ̀ (Ẹsr 7:10; w00 10/1 14 ¶8)

Àwọn èèyàn rí i pé Ọlọ́run fún Ẹ́sírà lọ́gbọ́n (Ẹsr 7:25; si 75 ¶5)

Ẹ́sírà rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ìyẹn mú kó dá a lójú pé Jèhófà máa tọ́ òun sọ́nà, á sì dáàbò bo òun (Ẹsr 8:21-23; it-1 1158 ¶4)

Àwọn ohun tí Ẹ́sírà ṣe fi hàn pé ó ní ọgbọ́n Ọlọ́run, ìyẹn sì mú kí ọba gbé àwọn iṣẹ́ pàtàkì fún un. Bíi ti Ẹ́sírà, àwa náà lè fi ìwà wa gbé orúkọ Jèhófà ga.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ìwà mi máa ń mú káwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀wọ̀ fún mi?’