MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
‘À Ń Gbèjà Ìhìn Rere, A sì Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin’
Nígbà táwọn alátakò fẹ́ dá iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì dúró, ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí, kí wọ́n lè lómìnira láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. (Ẹsr 5:11-16) Bákan náà lónìí, àwa Kristẹni máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbèjà ìhìn rere, ká sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin. (Flp 1:7) Torí náà lọ́dún 1936, a dá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin sílẹ̀ ní orílé-iṣẹ́ wa ká lè máa fi gbèjà ìhìn rere. Lónìí, ẹ̀ka yìí máa ń ṣètò bá a ṣe lè gbèjà ìhìn rere kárí ayé. Àwọn nǹkan wo ni ẹ̀ka yìí ti ṣe kí iṣẹ́ ìwàásù lè máa tẹ̀ síwájú, káwa èèyàn Ọlọ́run sì lómìnira láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌBẸ̀WÒ SÍ Ẹ̀KA TÓ Ń RÍ SỌ́RỌ̀ ÒFIN LÓRÍLÉ-IṢẸ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Àwọn ìṣòro wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dojú kọ lábẹ́ òfin?
-
Àwọn àṣeyọrí wo la sì ti ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan
-
Kí ni àwa náà lè ṣe láti ‘gbèjà ìhìn rere, ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’?
-
Ibo lórí ìkànnì wa lo ti lè rí ìsọfúnni nípa ọ̀rọ̀ òfin tó kan àwa èèyàn Ọlọ́run àti orúkọ àwọn ará wa tí wọ́n ti fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn?