ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
‘Ẹ Má Ṣe Dí Iṣẹ́ Náà Lọ́wọ́’
Jéṣúà (tàbí Jóṣúà) Àlùfáà Àgbà àti Gómínà Serubábélì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì láìka àṣẹ ọba tí wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ náà sí (Ẹsr 5:1, 2; w22.03 18 ¶13)
Nígbà táwọn alátakò béèrè ẹni tó fún wọn láṣẹ láti kọ́ ilé náà, àwọn Júù tọ́ka sí àṣẹ tí Ọba Kírúsì pa (Ẹsr 5:3, 17; w86 6/1 29, àpótí ¶2-3)
Ọba náà ṣèwádìí, ó sì rí i pé lóòótọ́ ni Ọba Kírúsì fún wọn láṣẹ láti kọ́ ilé náà, ó wá pàṣẹ fáwọn alátakò náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ dí iṣẹ́ náà lọ́wọ́ (Ẹsr 6:7, 8; w22.03 15 ¶7)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni ìtàn Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni àwọn tí Jèhófà yàn láti máa bójú tó wa, kódà tí ohun tí wọ́n ní ká ṣe ò bá fi bẹ́ẹ̀ yé wa?—w22.03 19 ¶16.