July 31–August 6
NEHEMÁYÀ 3-4
Orin 143 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ṣé Ó Máa Ń Yá Ẹ Lára Láti Ṣe Iṣẹ́ Tó Dà Bíi Pé Ó Rẹlẹ̀?”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
Ne 4:17, 18—Báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè máa fi ọwọ́ kan ṣoṣo mọ ògiri? (w06 2/1 9 ¶1)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Ne 3:15-24 (th ẹ̀kọ́ 2)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Àkòrí ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni kó o fi bẹ̀rẹ̀. Ẹni náà sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Jíròrò ẹ̀yìn ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì, kó o sì béèrè bóyá ẹni náà máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 12)
Àsọyé: (5 min.) km 11/12 1—Àkòrí: Máa Rí Ohun Rere Nínú Iṣẹ́ Àṣekára Rẹ. (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Wọ́n Bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣiṣẹ́: (8 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà béèrè pé, Kí lo rí nínú fídíò yìí tó jẹ́ kó o gbà pé ìwà wa níbiṣẹ́ lè mú káwọn míì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (7 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lff ẹ̀kọ́ 52
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 29 àti Àdúrà