ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ṣé Ó Máa Ń Yá Ẹ Lára Láti Ṣe Iṣẹ́ Tó Dà Bíi Pé Ó Rẹlẹ̀?
Àlùfáà àgbà àtàwọn arákùnrin rẹ̀ ò jọ ara wọn lójú, wọn ò sì ronú pé kì í ṣe irú àwọn ló yẹ kí wọ́n bá nídìí iṣẹ́ kíkọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù (Ne 3:1)
Àwọn olókìkí kan láàárín wọn kọ̀ láti “rẹ ara wọn sílẹ̀,” wọn ò sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà (Ne 3:5; w06 2/1 10 ¶1)
Àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ tó lágbára, tó sì léwu yìí (Ne 3:12; w19.10 23 ¶11)
Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tá à ń ṣe nínú ìjọ ló jẹ́ iṣẹ́ alágbára tàbí iṣẹ́ tó dà bíi pé ó rẹlẹ̀, àwọn èèyàn sì lè má rí wa nígbà tá a bá ń ṣe é.—w04 8/1 18 ¶16.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti ṣe irú àwọn iṣẹ́ yìí?’—1Kọ 9:23.