Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

August 19-25

SÁÀMÙ 75-77

August 19-25

Orin 120 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Gbéra Ga?

(10 min.)

Jèhófà kórìíra kéèyàn máa gbéra ga (Sm 75:4; 1Ti 3:6; w18.01 28 ¶4-5)

Tá a bá láǹfààní tàbí ojúṣe èyíkéyìí nínú ìjọ, ká fi sọ́kàn pé ẹ̀bùn tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ló jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà (Sm 75:5-7; w06 7/15 11 ¶3)

Jèhófà máa rẹ àwọn agbéraga wálẹ̀, irú bí àwọn ọba ayé tí wọ́n máa ń ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ (Sm 76:12)

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 76:10—Báwo ni “ìrunú èèyàn” ṣe lè yọrí sí ìyìn fún Jèhófà? (w06 7/15 11 ¶4)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi fídíò kan han ẹni náà lórí ìkànnì jw.org ní èdè tó fẹ́, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Bẹ́ ẹ ṣe ń bọ́rọ̀ lọ, ẹni náà sọ pé òun ò gba Ọlọ́run gbọ́, yí ọ̀rọ̀ ẹ pa dà, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ bá ipò ẹ̀ mu. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 127

7. Jẹ́ Adúróṣinṣin Nígbà Tí Wọ́n Bá Ń Yìn Ọ́

(7 min.) Ìjíròrò.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Jẹ́ Adúróṣinṣin Bíi Jésù—Nígbà Tí Wọ́n Bá Ń Yìn Ọ́. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Sergei gbà fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń yìn ín?

8. Àkànṣe Ìwàásù Láti Fi Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣù September

(8 min.) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ̀rọ̀ lọ́nà táá jẹ́ kó wu àwọn ará láti kópa nínú àkànṣe ìwàásù náà, kó o sì sọ ètò tí ìjọ ti ṣe.

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 95 àti Àdúrà