August 26–September 1
SÁÀMÙ 78
Orin 97 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìkìlọ̀ Ni Ìwà Àìṣòótọ́ Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Jẹ́ fún Wa
(10 min.)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Jèhófà ṣe (Sm 78:11, 42; w96 12/1 29-30)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè fún wọn (Sm 78:19; w06 7/15 17 ¶16)
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wọn, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n sọ ìwà burúkú dàṣà (Sm 78:40, 41, 56, 57; w11 7/1 10 ¶3-4)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Kí ni ò ní jẹ́ ká di aláìṣòótọ́ sí Jèhófà?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 78:24, 25—Kí nìdí tí Bíbélì fi pe mánà ní “ọkà ọ̀run” àti “oúnjẹ àwọn alágbára”? (w06 7/15 11 ¶5)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 78:1-22 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìléwọ́ wa bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(1 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé kó o má jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ gùn jù. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)
7. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Wá ọ̀nà tó o lè gbà jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ láìjẹ́ pé o mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ Bíbélì, kó o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
Orin 96
8. Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Fílípì Ajíhìnrere
(15 min.) Ìjíròrò.
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó ṣe ohun rere àtàwọn tó ṣe búburú ló wà nínú Bíbélì. Ó máa gba àkókò àti ìsapá ká tó lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ yẹn. Yàtọ̀ sí kíka àwọn ìtàn Bíbélì yìí, ó tún yẹ ká ronú lórí ohun tá a kà, ká sì fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa.
Àwọn èèyàn mọ Fílípì ajíhìnrere sí Kristẹni tó “kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n.” (Iṣe 6:3, 5) Kí la lè kọ́ lára ẹ̀?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Wọn—Fílípì Ajíhìnrere. Lẹ́yìn náà, béèrè ohun táwọn ará kọ́ nínú àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:
-
Kí ni Fílípì ṣe nígbà tí nǹkan yí pa dà fún un?—Iṣe 8:1, 4, 5
-
Àwọn ìbùkún wo ni Fílípì rí torí pé ó lọ sìn níbi tí àìní wà?—Iṣe 8:6-8, 26-31, 34-40
-
Àǹfààní wo ni Fílípì àti ìdílé ẹ̀ rí torí pé wọ́n gba àwọn míì lálejò?—Iṣe 21:8-10
-
Àǹfààní wo ni ìdílé inú fídíò náà rí torí pé wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Fílípì?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 14 ¶11-20