Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

August 5-11

SÁÀMÙ 70-72

August 5-11

Orin 59 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Sọ Nípa Agbára Ọlọ́run “fún Ìran Tó Ń Bọ̀”

(10 min.)

Jèhófà dáàbò bo Dáfídì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ (Sm 71:5; w99 9/1 18 ¶17)

Jèhófà dúró ti Dáfídì nígbà tó darúgbó (Sm 71:9; g04 10/8 23 ¶3)

Dáfídì sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i fáwọn ọ̀dọ́ kó lè fún wọn níṣìírí (Sm 71:17, 18; w14 1/15 23 ¶4-5)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Èwo nínú àwọn tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún nínú ìjọ wa ni mo lè fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé wa?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 72:8—Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù ní Jẹ́nẹ́sísì 15:18 ṣe ṣẹ nígbà tí Ọba Sólómọ́nì ń ṣàkóso? (it-1 768)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà bẹ̀rẹ̀ sí í jiyàn, dá ọ̀rọ̀ rẹ dúró lọ́nà pẹ̀lẹ́. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Kàn sí mọ̀lẹ́bí rẹ kan tẹ́ ẹ ti jọ sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, bẹ́ ẹ ṣe ń bọ́rọ̀ lọ, o kíyè sí i pé kò wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 4)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àsọyé. ijwfq 49—Àkòrí: Kí Ló Fà Á Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Yí Àwọn Ohun Kan tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Pa Dà? (th ẹ̀kọ́ 17)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 76

7. Àwọn Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Ṣe Nígbà Ìjọsìn Ìdílé

(15 min.) Ìjíròrò.

Ìjọsìn Ìdílé jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan táwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn ní “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Ef 6:4) Kì í rọrùn láti kẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ àwọn òbí lè mú káwọn ọmọ wọn gbádùn Ìjọsìn Ìdílé, pàápàá tó bá ń wu àwọn ọmọ náà láti túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jo 6:27; 1Pe 2:2) Káwọn òbí lè mọ bí wọ́n ṣe lè mú kí Ìjọsìn Ìdílé gbádùn mọ́ni, káwọn tó wà níbẹ̀ sì rí ẹ̀kọ́ kọ́, ẹ wo àpótí náà “ Àwọn Àbá Tẹ́ Ẹ Lè Lò fún Ìjọsìn Ìdílé,” kẹ́ ẹ sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Èwo nínú àwọn àbá tó wà níbí ni wàá fẹ́ gbìyànjú?

  • Àwọn nǹkan míì wo lẹ ti ṣe tó o gbà pé ó dáa fún ìjọsìn ìdílé?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ẹ Jẹ́ Kí Ìjọsìn Ìdílé Yín Túbọ̀ Gbádùn Mọ́ni. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni ọkọ kan ṣe lè mú kí ìyàwó ẹ̀ gbádùn ìjọsìn ìdílé tí wọ́n bá wà láwọn nìkan?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 13 ¶17-24

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 123 àti Àdúrà