Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

July 1-7

SÁÀMÙ 57-59

July 1-7

Orin 148 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọba Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n lépa Dáfídì, tí wọn ò sì rí i mú

1. Jèhófà Máa Ń Jẹ́ Kí Ìsapá Àwọn Alátakò Já sí Asán

(10 min.)

Dáfídì ní láti fara pa mọ́ torí Ọba Sọ́ọ̀lù ń lépa ẹ̀mí ẹ̀ (1Sa 24:3; Sm 57, àkọlé)

Jèhófà jẹ́ kí ìsapá àwọn ọ̀tá Dáfídì já sí asán (1Sa 24:7-10, 17-22; Sm 57:3)

Ohunkóhun táwọn alátakò bá ṣe sábà máa ń pa dà bu wọ́n lọ́wọ́ (Sm 57:6; bt 220-221 ¶14-15)

BI ARA RẸ PÉ, ‘Kí ni mo lè ṣe táá fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà táwọn èèyàn bá ń ta kò mí?’—Sm 57:2.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 57:7—Kí ló túmọ̀ sí láti ní ọkàn tó dúró ṣinṣin? (w23.07 18-19 ¶16-17)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ—Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 1-2.

5. Má Jẹ́ Kó Sú Ẹ—Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 65

6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 78 àti Àdúrà