ÌGBÉ AYÉ KRISTẸNI
Ọgọ́rùn-ún Ọdún Ti Kọjá, Ìjọba Ọlọ́run Ṣì Ń Ṣàkóso!
Àwọn tó bá fẹ́ di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́ nípa Ìjọba náà àtàwọn ohun tó ti gbé ṣe. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso, á sì tún jẹ́ kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. (Sm 45:1; 49:3) Ẹ wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Ti Kọjá, Ìjọba Ọlọ́run Ṣì Ń Ṣàkóso, kẹ́ ẹ sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
-
Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìbùkún ní “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” jẹ́ fún àwọn tó wò ó?
-
Báwo la ṣe lo rédíò láti wàásù ìhìn rere?
-
Àwọn ọ̀nà míì wo la gbà wàásù ìhìn rere, kí ló sì yọrí sí?
-
Báwo la ṣe ń mú kí ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìwàásù sunwọ̀n sí i?
-
Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́ wo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ń gbà?
-
Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi àpéjọ àgbègbè dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́?
-
Kí ló jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso?
-
Báwo la ṣe lè ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn?