June 6 sí 12
SÁÀMÙ 34-37
Orin 95 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere”: (10 min.)
Sm 37:1, 2
—Pọkàn pọ̀ sórí bó o ṣe ń sin Jèhófà, má ṣe wo àṣeyọrí àwọn aṣebi tí kì í tọ́jọ́ (w03 12/1 ojú ìwé 9 àti 10 ìpínrọ̀ 3 sí 6) Sm 37:3-6
—Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, máa ṣe rere, kó o sì gba ìbùkún (w03 12/1 ojú ìwé 10 sí 12 ìpínrọ̀ 7 sí 15) Sm 37:7-11
—Fi sùúrù dúró de Jèhófà láti mú àwọn ẹni burúkú kúrò (w03 12/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 16 sí 20)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 34:18
—Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń bójú tó àwọn “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” àti “àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀”? (w11 6/1 ojú ìwé 19) Sm 34:20
—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jésù lára? (w13 12/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 19) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 35:19–36:12
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n kọ àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wọn sílẹ̀.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 93
“Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I
—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́”: (15 min.) Ìjíròrò. Fi fídíò tó wà lórí ìkànnì jw.org/yo tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì? ṣàlàyé àwọn kókó tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Bó O Ṣe Lè Ṣe É.” (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLA ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ. Lẹ́yìn náà, lọ síbi tí ìwé Ìròyìn Ayọ̀ wà, kó o sì ṣí i. Wàá rí fídíò náà lábẹ́ ẹ̀kọ́ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Ìròyìn Ayọ̀ Ti Wá Lóòótọ́?”) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 17 ìpínrọ̀ 1 sí 13
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 61 àti Àdúrà