Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Kí O sì Máa Ṣe Rere
“Má ṣe ìlara àwọn tí ń ṣe àìṣòdodo”
-
Má ṣe jẹ́ kí àṣeyọrí tí kì í tọ́jọ́ táwọn ẹni burúkú ṣe mú kó o ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìbùkún tẹ̀mí àtàwọn àfojúsùn tẹ̀mí
“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”
-
Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà máa ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o bá ń ṣàníyàn tàbí ṣiyèméjì. Ó máa ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀
-
Máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run
“Máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà”
-
Ṣètò àkókò rẹ láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà lọ́nà tí wàá fi lè túbọ̀ mọ Jèhófà
‘Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́’
-
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bójú tó ìṣòro èyíkéyìí tó o bá ní
-
Máa hùwà tó dára kódà tí wọ́n bá ń ta kò ọ́, tí wọ́n ń ṣenúnibíni sí ọ tàbí tí wọ́n ń sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ nípa rẹ
“Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà, kí o sì fi ìyánhànhàn dúró dè é”
-
Yẹra fún fífi ìwàǹwára ṣe nǹkan. Ó lè ba ayọ̀ rẹ jẹ́, ó sì lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́
“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé”
-
Túbọ̀ máa jẹ́ ọkàn tútù, kó o sì fi ìrẹ̀lẹ̀ dúró de Jèhófà títí tó fi máa mú gbogbo àìṣèdájọ́-òdodo tí wọ́n ṣe sí ọ kúrò
-
Máa ṣètìlẹ́yìn fáwọn onígbàgbọ́ bíi tìẹ, kó o sì máa fi ìlérí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣe, tí kò ní pẹ́ dé mọ́ tu àwọn tó sorí kọ́ nínú