Baba àti ìyá kan lórílẹ̀-èdè South Africa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI June 2018

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ìjíròrò tó dá lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti ọjọ́ ìkẹyìn.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣẹ sí Jésù Lára

Kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára mu.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Tẹ̀ Lé Ìṣísẹ̀ Kristi Pẹ́kípẹ́kí

Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé, ní pàtàkì tá a bá ń kojú àdánwò tàbí inúnibíni.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Màríà

Jèhófà yan Màríà pé kó ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan tí kò tí ì sí ẹni tó ṣe irú ẹ̀ rí, tí kò sì ní sí ẹni tó máa ṣe irú ẹ̀ torí pé ó ní ọkàn rere tó ṣàrà ọ̀tọ̀.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Àjọṣe Yín Pẹ̀lú Jèhófà Túbọ̀ Ń Lágbára Sí I?

Jésù ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá di ọ̀rọ̀ ká sin Jèhófà àti ká bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí ẹni.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí

O lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run tó o bá ń lo gbogbo àyè tó bá yọ láti kọ́ wọn.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Kọ Ìdẹwò Bí I Ti Jésù

Ohun ìjà tó lágbára wo ni Jésù lò láti fi borí àwọn ìdẹwò mẹ́ta tí Sátánì sábà máa ń lò?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò

Bí ọ̀pọ̀ ohun èlò, ìkànnì àjọlò wúlò lápá kan, ó sì léwu lápá kan. A lè lo àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti rí àwọn ewu tó wà níbẹ̀, ká sì yẹra fún wọn.