June 18-24
Lúùkù 2-3
Orin 133 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Àjọṣe Yín Pẹ̀lú Jèhófà Túbọ̀ Ń Lágbára Sí I?”: (10 min.)
Lk 2:41, 42—Jésù àti àwọn òbí rẹ̀ jọ máa ń lọ sí àjọyọ̀ Ìrékọjá ọdọọdún (“ó jẹ́ àṣà àwọn òbí rẹ̀” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:41, 42, nwtsty)
Lk 2:46, 47—Jésù tẹ́tí sí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ó sì bi wọ́n ní ìbéèrè (“ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè,” “wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:46, 47, nwtsty)
Lk 2:51, 52—Jésù “ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́” àwọn òbí rẹ̀, ó sì rí ojú rere Ọlọ́run àti èèyàn (“bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:51, 52, nwtsty)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Lk 2:14—Kí ni ìtumọ̀ Lúùkù 2:14? (“àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà,” “àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 2:14, nwtsty)
Lk 3:23—Ta ni bàbá Jósẹ́fù? (wp16.3 9 ¶1-3)
Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lk 2:1-20
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà, dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù.
Ìpadàbẹ̀wò Kejì—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.
Àsọyé: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) w14 2/15 26-27—Àkòrí: Kí Ló Mú Kí Àwọn Júù Ọ̀rúndún Kìíní Máa “Fojú Sọ́nà” fún Mèsáyà?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣàṣeyọrí”: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Wọ́n Gbá Àǹfààní Tó Ṣí Sílẹ̀ Mú.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) lv orí 9 ¶1-12 àti Ohun Tó Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Ìṣekúṣe [Kò pọn dandan kẹ́ ẹ ka àpótí tàbí àfikún àlàyé]
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 17 àti Àdúrà