Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kí Ni Jèhófà Máa Fẹ́ Kí N Ṣe?

Kí Ni Jèhófà Máa Fẹ́ Kí N Ṣe?

Ká tó ṣe ìpinnu, ó kéré ni, ó pọ̀ ni, á dáa ká bi ara wa pé, ‘Kí ni Jèhófà máa fẹ́ kí n ṣe?’ Lóòótọ́ kò sí báa ṣe lè mọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn Jèhófà, àmọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ti jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tá a nílò ká lè gbára dì fún “gbogbo iṣẹ́ rere.” (2Ti 3:​16, 17; Ro 11:​33, 34) Jésù fòye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́, ó sì fi ìfẹ́ Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀. (Jo 4:34) Bíi ti Jésù, àwa náà lè ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè máa ṣe ìpinnu táá múnú Jèhófà dùn.​—Jo 8: 28, 29; Ef 5:​15-17.

WO FÍDÍÒ NÁÀ Ẹ MÁA FI ÒYE MỌ OHUN TÍ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ JẸ́ (LE 19:18), KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wa?

  • Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan orin tá a máa gbọ́?

  • Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ yan aṣọ tá a máa wọ̀ àti ìmúra wa?

  • Àwọn apá wo ní ìgbésí ayé wa ló tún yẹ ká ti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò?

  • Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe?

Kí ni àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe ń sọ nípa àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?