“Àkàwé” Kan àti Ìtumọ̀ Rẹ̀
Pọ́ọ̀lù lo “àkàwé” yìí láti jẹ́ ká mọ̀ pé májẹ̀mú tuntun kì í ṣẹgbẹ́ májẹ̀mú Òfin. Lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ Kristi àtàwọn tó máa bá a jọba, gbogbo aráyé máa gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àìpé, ìbànújẹ́ àti ikú.—Ais 25:8, 9.
ẸRÚ NÁÀ HÁGÁRÌ Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, Jerúsálẹ́mù sì ni olú ìlú rẹ̀ |
SÁRÀ—OBÌNRIN TÓ LÓMÌNIRA Jerúsálẹ́mù ti òkè, apá ti ọ̀run lára ètò Ọlọ́run |
ÀWỌN “ỌMỌ” HÁGÁRÌ Àwọn Júù (tó ṣèlérí pé àwọn á máa tẹ̀ lé májẹ̀mú Òfin) kọ Jésù, wọ́n sì pa á |
ÀWỌN “ỌMỌ” SÁRÀ Kristi àti àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) |
MÁJẸ̀MÚ ÒFIN TÓ MÚNI LẸ́RÚ Òfin yẹn ló ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n jẹ́ |
MÁJÈMÚ TUNTUN TÓ SỌNI DI ÒMÌNIRA Ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi máa dáni sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdálẹ́bi Òfin, á sì sọni di òmìnira |