MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀kọ́ Wo Ló Lè Kọ́ Lára Àwọn Kristẹni Tó Nírìírí?
Nínú àwọn ìjọ wa, a láwọn tó ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ọdún. A sì lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. A lè bi wọ́n nípa ìtàn àwa èèyàn Jèhófà àtàwọn ìṣòro tí Jèhófà ti mú kí wọ́n borí. A tiẹ̀ lè pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wá sí Ìjọsìn Ìdílé wa, ká sì ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní.
Tó bá jẹ́ pé o ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run, o lè sọ àwọn ìrírí tó o ti ní fáwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́. Jékọ́bù àti Jósẹ́fù náà sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní fáwọn míì. (Jẹ 48:21, 22; 50:24, 25) Nígbà tó yá, Jèhófà pàṣẹ pé káwọn olórí ìdílé máa kọ́ àwọn ọmọ wọn láwọn nǹkan àgbàyanu tóun ti ṣe. (Di 4:9, 10; Sm 78:4-7) Lákòókò wa yìí, àwọn òbí àtàwọn míì nínú ìjọ lè kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láwọn nǹkan àgbàyanu tí wọ́n ti rí tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ ètò rẹ̀.
WO FÍDÍÒ NÁÀ A WÀ NÍṢỌ̀KAN BÍ WỌ́N TILẸ̀ FÒFIN DÈ WÁ, LẸ́YÌN NÁÀ, DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Austria ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa?
-
Kí làwọn ará tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára?
-
Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn ará ní Ròmáníà fi ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ètò Ọlọ́run, báwo sì ni wọ́n ṣe pa dà?
-
Báwo làwọn ìrírí yìí ṣe fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun?