Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Bá A Ṣe Lè Lo Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Láti January 2018 ni apá tá a pè ní ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ti máa ń wà níwájú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. Báwo la ṣe lè lò ó?

Tó O Bá Níṣẹ́ Ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́: Lo ìbéèrè, Bíbélì àti ìbéèrè fún ìgbà míì bó ṣe wà nínú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú fídíò ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ni ìwọ náà gbọ́dọ̀ lò. O lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tàbí kó o lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀. Ó sì lè jẹ́ pé kókó míì ló máa tẹnu mọ́ nínú iṣẹ́ náà. Ó tún lè fún onílé ní ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, kódà tí ìtọ́ni fún iṣẹ́ náà ò bá sọ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀.

Tá A Bá Wà Lóde Ẹ̀rí: A ṣètò apá ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ ká lè mọ onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, tó sì fẹ́ ká pa dà wá, a lè lo ìbéèrè tá a máa bi onílé nígbà ìpadàbẹ̀wò. A lè ṣàtúnṣe díẹ̀ sí ìbéèrè yìí tàbí ká tiẹ̀ lo ìbéèrè míì tó yàtọ̀ pátápátá. Ṣé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín máa nífẹ̀ẹ́ sí kókó míì tàbí ẹsẹ Bíbélì kan tẹ́ ẹ ti lò láwọn oṣù tó ti kọjá? Ṣé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbègbè wọn? Ọ̀nà yòówù ká gbà lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ, ohun tó yẹ kó jẹ wá lọ́kàn ni bá a ṣe máa ‘ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, ká lè sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.’​—1Kọ 9:22, 23.