Jóòbù Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Rẹ̀
Jóòbù ò ní dúkìá kankan mọ́, ó ti pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀, àìsàn burúkú kan ń ṣe é, síbẹ̀ ó ṣì jẹ́ olóòótọ́. Sátánì gbìyànjú láti mú kí Jóòbù rẹ̀wẹ̀sì kó lè ba ìṣòtítọ́ rẹ̀ jẹ́. Àwọn “ọ̀rẹ́” rẹ̀ mẹ́ta dé. Wọ́n kọ́kọ́ ṣe bí ẹni pé wọ́n fẹ́ bá a kẹ́dùn. Wọ́n wá jókòó ti Jóòbù fún ọjọ́ méje láì sọ̀rọ̀ ìtùnú kankan fún un. Ìgbà tí wọ́n tún máa sọ̀rọ̀, ńṣe ni wọ́n fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀sùn kàn án.
Jóòbù pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́ láì ka ìdààmú tó bá a sí
-
Ìbànújẹ́ tó lágbára tó bá Jóòbù mú kó ronú lọ́nà tí kò tọ́. Èrò tí kò tọ́ tó ní yìí mú kó ronú pé ìwà títọ́ òun kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run
-
Torí ìrẹ̀wẹ̀sì tó dé bá Jóòbù, kò ronú lórí ohun tó ṣeé ṣe kó fa ìyà tó ń jẹ ẹ́
-
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbànújẹ́ dorí Jóòbù kodò, ó ṣì sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fáwọn tó fẹ̀sùn kàn án