MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìràpadà Mú Kí Àjíǹde Ṣeé Ṣe
Ìrántí Ikú Jésù máa ń fún wa láǹfààní láti ronú lórí àwọn ìbùkún tí ìràpadà máa jẹ́ ká rí gbà lọ́jọ́ iwájú, irú bí àjíǹde. Jèhófà ò fẹ́ ká máa kú rárá. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ikú èèyàn ẹni wà lára ohun tó máa ń dunni jù lọ. (1Kọ 15:26) Ó dun Jésù nígbà tó rí i tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù. (Jo 11:33-35) Torí pé Jésù jọ Baba rẹ̀ délẹ̀délẹ̀, ó dá wa lójú pé ó máa dun Jèhófà tó bá ń rí i tá à ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wa kan tó kú. (Jo 14:7) Ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dìde nínú ikú, ó yẹ kó máa wu àwa náà bẹ́ẹ̀.—Job 14:14, 15.
Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run ètò, a lè retí pé àjíǹde máa wà létòlétò. (1Kọ 14:33, 40) Dípò ká máa lọ síbi ìsìnkú, ó ṣeé ṣe kí ètò wà láti máa kí àwọn tó ti kú káàbọ̀. Ǹjẹ́ o máa ń ronú nípa àjíǹde ní pàtàkì jù lọ nígbà tó o bá ń ṣọ̀fọ̀? (2Kọ 4:17, 18) Ṣé o máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe pèsè ìràpadà tó sì jẹ́ ká rí i nínú Ìwé Mímọ́ pé àwọn òkú yóò jíǹde?—Kol 3:15.
-
Àwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ wo lo máa kọ́kọ́ fẹ́ rí nígbà àjíǹde?
-
Àwọn wo lára àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn lo máa fẹ́ rí kó o sì bá sọ̀rọ̀?