March 7 sí 13
Ẹ́SÍTÉRÌ 6-10
Orin 131 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ẹ́sítérì Kò Mọ Tara Rẹ̀ Nìkan, Ó Gbèjà Jèhófà Àtàwọn Èèyàn Rẹ̀”: (10 min.)
Ẹst 8:3, 4
—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú yẹ̀ lórí Ẹ́sítérì, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu nítorí àwọn ẹlòmíì (ia ojú ìwé 143 ìpínrọ̀ 24 àti 25) Ẹst 8:5—Ẹ́sítérì fọgbọ́n bá Ahasuwérúsì sọ̀rọ̀ (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 8)
Ẹst 8:17—Ọ̀pọ̀ àwọn ará Páṣíà di aláwọ̀ṣe Júù (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 3)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ẹst 8:1, 2
—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ kó tó kú pé ‘Bẹ́ńjámínì yóò pín ohun ìfiṣèjẹ ní ìrọ̀lẹ́’ ṣe ṣẹ? (ia ojú ìwé 142, àpótí) Ẹst 9:10, 15, 16
—Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin fàyè gba àwọn Júù láti kó àwọn ìkógun, kí nìdí tí wọ́n fi kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀? (w06 3/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Ẹst 8:1-9 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Múra Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Oṣù Yìí Sílẹ̀: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, kó o sì jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn fídíò náà. Lẹ́yìn náà, jíròrò àpilẹ̀kọ náà “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Kọ Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó O Fẹ́ Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni.”
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 118
“Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀”: (15 min.) Ìjíròrò. Ní kí àwọn ara sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní lẹ́yìn tí wọ́n lo ìdánúṣe láti kí àwọn tá a pè sí Ìrántí Ikú Kristi tó kọjá káàbọ̀. Ní kí ẹni tó sọ ìrírí tó gbádùn mọ́ni jù lọ ṣe àṣefihàn ìrírí rẹ̀.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 10 ìpínrọ̀ 12 sí 21 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 91 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 147 àti Àdúrà