Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀

Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀

À ń retí àwọn mílíọ̀nù méjìlá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tá a fi ìwé pè sí Ìrántí ikú Kristi tó máa wáyé ní March 23. Ó dájú pé àwọn tá a pè máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ gan-an bí alásọyé á ṣe sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà pèsè àtàwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú tí ìràpadà máa mú kó ṣeé ṣe fún aráyé! (Ais 11:6-9; 35:5, 6; 65:21-23; Jo 3:16) Àmọ́, kì í ṣe àsọyé tí alásọyé ọjọ́ náà bá sọ nìkan láá jẹ́rìí fáwọn tá a pè wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. Gbogbo wa pátá ló yẹ ká fi ọ̀yàyà kí àwọn tá a pè káàbọ̀. (Ro 15:7) Àwọn ohun tá a lè ṣe rèé.

  • Dípò tí wàá fi lọ jókòó sí àyè rẹ tí wàá sì máa retí kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ̀rẹ̀, lọ kí àwọn tá a pè àtàwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tó wá káàbọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ àti ọ̀yàyà

  • Bó o ṣe ń kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó o dìídì pè, má ṣe gbàgbé láti kí àwọn míì tó wá torí pé a pín ìwé ìkésíni dé ọ̀dọ̀ wọn. Sọ pé kí wọ́n wá jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ. Ẹ jọ lo Bíbélì àti ìwé orin rẹ

  • Lẹ́yìn àsọyé, wá àyè láti dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bá ní. Tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ sí àyè bóyá torí pé wọ́n ní kẹ́ ẹ tètè jáde kí àwọn ìjọ míì lè wọlé, ó máa dára tó o bá ṣètò láti lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni náà lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀. Tó ò bá mọ ibi tí ẹni náà ń gbé, o lè sọ pé: “Màá fẹ́ mọ bẹ́ ẹ ṣe gbádùn ìpàdé yìí sí. Báwo ni mo ṣe lè kàn sí yín?”