Wọ́n ń pe àwọn èèyàn síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní Albania

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI March 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọni àti láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Mo Wà Pẹ̀lú Rẹ Láti Dá Ọ Nídè”

Jeremáyà ronú pé òun ò tóótun láti gba iṣẹ́ wòlí ì tí Jèhófà Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́. Báwo ni Jèhófà ṣe fí i lọ́kàn?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Wọn Ò Ṣe Ohun Tí Jèhófà Fẹ́ Mọ́

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pé àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú lè bo ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Àmọ́ Jeremáyà tú àṣírí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ìwà àgàbàgebè wọn.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

Lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti fi jẹ́ kí àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa, kí wọ́n sì mọ̀ nípa ohun tí à ń ṣe àti ètò wa.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Tá A Bá Tẹ̀lé Ìtọ́sọ́nà Jèhófà Nìkan La Máa Ṣàṣeyọrí

Nílẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn tó tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà wà níṣọkàn, wọ́n láyọ̀, wọ́n sì ṣàṣeyọrí.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run

Lo àwọn àwòrán àtàwọn ẹsẹ Bíbélì láti kọ́ àwọn tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Pa Jèhófà Tì

Kí ni Jèhófà Ọlọ́run ń ṣàpẹẹrẹ nígbà tó sọ fún Jeremáyà pé kó rìrìn àjò 500 kìlómítà lọ sí Odò Yúfírétì láti lọ fi ìgbànú aṣọ ọ̀gbọ kan pamọ́ síbẹ̀?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Máa Rántí Jèhófà

Tí ẹ bá ń ṣe ìjọsìn Ìdílé déédéé, tó sì nítumọ̀, èyí máa ran ìdílé yín lọ́wọ́ láti máa rántí Jèhófà. Báwo lo ṣe lè rí i dájú pé kò sí ohun tó máa dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe Ìjọsìn Ìdílé?