Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?

A ṣe ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Wo Ló Ń ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní? ká lè jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú akẹ́kọ́ọ̀ ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ̀ọ̀kan. * Ẹ̀kọ́ 1 sí 4 máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ irú èèyàn tá a jẹ́, ẹ̀kọ́ 5 sí 14 máa jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan tí à ń ṣe, ẹ̀kọ́ 15 sí 28 sì máa ṣàlàyé ohun tí ètò wa ń gbéṣe fún wọn. Ó máa dáa ká jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ yìí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àyàfi tó bá gba pé ká jíròrò apá kan ní kíá. Ojú ìwé kan ni ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan wà, a sì lè lo ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá láti jíròrò ẹ̀kọ́ kan.

  • Pe àfíyèsí akẹ́kọ́ọ̀ sí ìbéèrè àkọ́kọ́ tó jẹ́ àkórí ẹ̀kọ́ náà

  • Ẹ jọ ka ẹ̀kọ́ náà papọ̀, ẹ lè kà á látòkè-délẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, ẹ sì lè ṣàlàyé ìpínrọ̀ kan kí ẹ tó ka ìpínrọ̀ tó tẹ̀lé e

  • Ẹ jọ jíròrò ohun tí ẹ kà. Béèrè àwọn ìbẹ́èrè tó wà nísàlẹ̀ ìwé, kí ẹ sì sọ̀rọ̀ lórí àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀. Àwa la máa pinnu èyí tá a máa kà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n tọ́ka sí, tá a sì máa ṣàlàyé. Sọ bí àwọn ìsọ̀rí tí wọ́n kọ lọ́nà tó dúdú yàtọ̀ ṣe dáhùn ìbéèrè tó jẹ́ àkórí ẹ̀kọ́ náà

  • Tí àpótí “Ṣe Ìwádìí Sí I” bá wà nínú ẹ̀kọ́ náà, ẹ jọ́ kà á, kó o sì gba akẹ́kọ̀ọ́ náà níyànjú pé kó tẹ̀lé àbá tó wà níbẹ̀

^ ìpínrọ̀ 3 A ti ṣe àwọn àtúnṣe díẹ̀ sí ẹ̀dà ìwé yìí tó wà lórí ìkànnì.