Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run

Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run

A ṣe ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run ká lè máa fi kọ́ àwọn èèyàn ní kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó sì ní onírúurú àwòrán nínú fún àǹfààní àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà. Ojú ìwé méjì ni ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ní, a sì fara balẹ̀ ya àwọn àwòrán sí i. Àwòrán kọ̀ọ̀kan ní àmí tó máa darí ìjíròrò látorí àwòrán kan sí òmíràn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé pọ̀ ju tinú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run lọ, àmọ́ àwòrán kan náà ló wà nínú ìwé méjèèjì. A lè fi ìwé yìí kọ́ ẹni tó mọ̀wé kà díẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn akéde máa ń lo ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ láti fi ṣàlàyé àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Àwọn ojú ìwé kan máa ń ní àpótí tí àfikún àlàyé wà nínú rẹ̀, ẹ lè lo àpótí yìí bí òye àkẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe lè gbé e tó.

A lè fi ìwé méjèèjì lọni lóde ẹ̀rí nígbàkigbà, kódà tí kì í bá ṣe òun là ń lò lóṣù náà. Tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lo àwọn àwòrán inú ìwé náà láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bi akẹ́kọ̀ọ́ ní ìbéèrè, kó o sì rí i pé ẹ̀kọ́ náà yé e dáadáa. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nísàlẹ̀ ojú ìwé kọ̀ọ̀kan, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ti parí ìwé náà, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kó o lè ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú débi táá fi ṣèrìbọmi.