Wọ́n ń pe ẹnì kan sí Ìrántí Ikú Kristi lórílẹ̀-èdè Slovenia

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI March 2018

Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ

Ìjíròrò tó dá lórí ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi àti ìbéèrè náà: Kí nìdí tí Jésù fi kú? Àǹfààní wo ni ìràpadà ṣe fún wa?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ẹnì Yòówù Tí Ó Bá Fẹ́ Di Ẹni Ńlá Láàárín Yín Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́ Yín”

Ṣé apá táwọn èèyàn á ti mọ̀ wá, tí wọ́n á sì ti máa yìn wá la máa ń fẹ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Òjíṣẹ́ tó nírẹ̀lẹ̀ á máa ṣe iṣẹ́ tó jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló ń rí i.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Àṣẹ Méjì Tó Tóbi Jù Lọ

Kí ni Jésù sọ pé ó jẹ́ àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ nínú Bíbélì? Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń pa àwọn àṣẹ náà mọ́?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bí A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Àtàwọn Aládùúgbò Wa

A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa. Ọ̀nà kan pàtàkì tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Máa Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Yìí

Ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ti jẹ́ kí ìgbé ayé ìdẹ̀rùn tí wọ́n ń lépa dí wọn lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí. Báwo làwọn Kristẹni tó wà lójúfò nípa tẹ̀mí ṣe yàtọ̀?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Òpin Ètò Àwọn Nǹkan Yìí Ti Sún Mọ́ Gan-an

Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣe fi hàn pé àkókò òpin là ń gbé? Ìdáhùn ìbéèrè yìí àti àwọn mí ì wà nínú fídíò Òpin Ètò Àwọn Nǹkan Yìí Ti Sún Mọ́ Gan-an.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”

Nínú àkàwé Jésù nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá, kí ni ọkọ ìyàwó, àwọn wúńdíá olóye àti àwọn òmùgọ̀ wúńdíá túmọ̀ sí? Kí ni àkàwé yìí kọ́ ẹ?

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sílẹ̀

Látìbẹ̀rẹ̀ ló yẹ ká ti ran àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n á ṣe máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sílẹ̀ kó lè mọ́ wọn lára. Báwo la ṣe lè ṣe é?