Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bí A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Àtàwọn Aládùúgbò Wa

Bí A Ṣe Lè Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Àtàwọn Aládùúgbò Wa

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Òfin Mósè làwa Kristẹni ń tẹ̀ lé, àmọ́ àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa, tó wà nínú òfin náà ṣe àkópọ̀ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. (Mt 22:​37-39) A kò lè ṣàdédé ní irú ìfẹ́ yẹn. Àfi ká sapá láti ní-in. Báwo la ṣe lè ní-in? Ọ̀nà pàtàkì kan ni pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ lórí onírúurú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní bí Bíbélì ṣe sọ, a máa rí “adùn Jèhófà.” (Sm 27:4) Ìyẹn á jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run lágbára sí i, a ó sì máa ronú bíi tiẹ̀. Èyí á sì máa jẹ́ kó wù wá láti pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tó fi mọ́ àṣẹ tó sọ pé ká ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ fún àwọn ẹlòmíì. (Jo 13:​34, 35; 1Jo 5:3) Àwọn àbá mẹ́ta kan rèé táá jẹ́ ká lè máa gbádùn Bíbélì kíkà:

  • Máa fi ọkàn yàwòrán ohun tí ò ń kà bíi pé ó wà níbẹ̀. Jẹ́ kó dà bí ẹni pé o wà níbẹ̀. Kí lo rí, ohùn wo lo gbọ́, òórùn wo lo gbọ́? Báwo ni ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn tí ìtàn náà dá lé?

  • Máa kà á lónírúurú ọ̀nà. Àwọn àbá kan rèé: Kà á sókè tàbí kó o máa fojú bá a lọ bó o ṣe ń gbọ́ èyí tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. Ka ìtàn ẹnì kan tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tàbí kó o kà nípa kókó kan dípò tí wàá fi máa ka àwọn orí Bíbélì bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ léra. Bí àpẹẹrẹ, o lè kà nípa Jésù ní Apá 4 tàbí Apá 16 nínú ìwé Àfikún Ìsọfúnni Láti Lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ka gbogbo orí Bíbélì tí ẹsẹ ojoojúmọ́ dá lé. Ká ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan bí àwọn ìtàn inú wọn ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra.

  • Kà á lọ́nà táá fi yé ẹ. Tó bá jẹ́ orí kan lo lè kà lójúmọ́, táá yé ẹ dáadáa, tí wàá sì lè ṣàṣàrò lé e lórí, ó dáa ju kó o máa ka orí Bíbélì tó pọ̀ torí pé o fẹ́ tètè parí Bíbélì. Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ kí ìtàn náà tó wáyé. Ronú jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tó wáyé nínú ìtàn náà. Wo máàpù àti àwọn atọ́ka etí ìwé. Ṣe ìwádìí lórí ohun kan tí kò yé ẹ nínú ibi tó o kà. Tó bá ṣeé ṣe, iye àkókò tó o bá fi ka Bíbélì náà ni kó o fi ṣàṣàrò lórí ohun tó o kà.