Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 22-23

Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Àṣẹ Méjì Tó Tóbi Jù Lọ

Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Àṣẹ Méjì Tó Tóbi Jù Lọ

22:​36-39

Ka Mátíù 22:​36-39, wo bí àwọn ìdí mẹ́ta tá a fi ń lọ sí àwọn ìpàdé wa tó wà nísàlẹ̀ yìí ti ṣe pàtàkì síra tó, kó o wá kọ ení, èjì, ẹ̀ta sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn:

  • Ká lè gba ìṣírí

  • Ká lè fún àwọn ará wa ní ìṣírí

  • Ká lè jọ́sìn Jèhófà, ká sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tiraka láti lọ sí àwọn ìpàdé wa kódà tó bá rẹ̀ wá, tá a sì ronú pé a ò lè fi bẹ́ẹ̀ jàǹfààní tá a bá lọ?

Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àṣẹ méjì tó tóbi jù náà?