Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sílẹ̀

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sílẹ̀

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bá múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sílẹ̀, èyí á jẹ́ kí wọ́n tètè lóye ohun tá à ń kọ́ wọn, kí wọ́n sì rántí rẹ̀. Bí wọ́n bá ṣe ń lóye àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́, tí wọ́n sì ń rántí rẹ̀ ni wọ́n á ṣe máa tẹ̀ síwájú tó. Kódà lẹ́yìn ìrìbọmi, wọ́n á ṣì máa múra àwọn ìpàdé àti òde ẹ̀rí sílẹ̀ kí wọ́n lè “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Mt 25:13) Torí náà, ó máa ṣe wọ́n láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn tí wọ́n bá mọ bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tó sì mọ́ wọn lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Látìbẹ̀rẹ̀ ló ti yẹ ká ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kó lè mọ́ wọn lára láti máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn sílẹ̀.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. (Ro 2:21) Ronú nípa ibi tí òye akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ bó o ṣe ń múra sílẹ̀ láti lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (km 11/15 3) Jẹ́ kó rí i pé ìwọ náà fa ìlà sí ìdáhùn nínú ìwé rẹ

  • Máa gbà á níyànjú pé kó múra sílẹ̀. Gbàrà tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni kó o ti jẹ́ kó mọ̀ pé ara ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ni ìmúrasílẹ̀, kó o sì jẹ́ kó mọ àwọn àǹfààní tó wà níbẹ̀. Sọ àwọn nǹkan tó lè ṣe kó lè máa ráyè múra ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ kàn lè gbà kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ìwé tí òun ti fàlà sí kó lè jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà rí àǹfààní tó wà níbẹ̀. Máa gbóríyìn fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ tó bá múra sílẹ̀

  • Fi bó ṣe máa múra sílẹ̀ hàn án. Látìbẹ̀rẹ̀ làwọn olùkọ́ kan ti máa ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n bá ṣe kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn bí wọ́n á ṣe máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sílẹ̀