Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

March 19-​25

MÁTÍÙ 24

March 19-​25
  • Orin 126 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Máa Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Yìí”: (10 min.)

    • Mt 24:12​—Ìwà àìlófin tó ń pọ̀ sí i máa jẹ́ kí ìfẹ́ àwọn èèyàn di tútù (it-2 279 ¶6)

    • Mt 24:39​—Bí àwọn kan ṣe máa gbé ìgbé ayé ìdẹ̀rùn ló máa gbà wọ́n lọ́kàn, tí wọn ò sì ní lè wà lójúfò (w99 11/15 19 ¶5)

    • Mt 24:44​—Ọ̀gá náà máa dé nígbà tí a kò rò tẹ́lẹ̀ (jy 259 ¶5)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Mt 24:8​—Kí ló ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Jésù yìí tọ́ka sí? (“ìroragógó wàhálà” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8, nwtsty)

    • Mt 24:20​—Kí nìdí tí Jésù fi sọ ọ̀rọ̀ yìí? (“ní ìgbà òtútù,” “ní ọjọ́ sábáàtì” àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:20, nwtsty)

    • Kí ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Mt 24:​1-22

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Dáhùn ìbéèrè kan táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ yín.

  • Ìpadàbẹ̀wò Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Ẹni tó o kọ́kọ́ wàásù fún kò sí nílé, àmọ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan lo bá.

  • Ìpadàbẹ̀wò Kejì​—Fídíò: (5 min.) Ẹ wo fídíò náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI