MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Kọ Lẹ́tà
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ìwé Kọ́ríńtì Kìíní jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn lẹ́tà mẹ́rìnlá tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ láti fún àwọn ará ní ìṣírí. Torí pé ẹni tá a kọ lẹ́tà sí máa kà á ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó yẹ kí ẹni tó ń kọ lẹ́tà náà fara balẹ̀ kọ ọ́. Ọ̀nà kan tó dáa tá a lè gbà wàásù fún àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ nìyẹn. A tún lè fi wàásù fún àwọn tá à ò lè rí bá sọ̀rọ̀ lójúkojú. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè fì ìfẹ́ hàn àmọ́ kó ṣòro bá nílé. Àwọn ilé kan lè má rọrùn láti dé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, àwọn míì sì lè jìnnà. Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ kó o fi sọ́kàn, pàápàá jù lọ tó o bá ń kọ lẹ́tà sí ẹni tó ò mọ̀ rí?
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
-
Ohun tó o fẹ́ bá ẹnì yẹn sọ ni kó o kọ sílẹ̀. Gbàrà tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà yẹn ni kó o ti sọ orúkọ rẹ. Sọ ìdí tó o fi ń kọ lẹ́tà náà, sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere. O lè bi ẹni náà ní ìbéèrè kan tó máa ronú lé lórí, kó o sì darí rẹ̀ sí ìkànnì wa. Lẹ́yìn náà, sọ fún un nípa Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, jẹ́ kó mọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń bá àwọn èèyàn ṣe nílé, o sì lè sọ àwọn àkòrí kan nínú àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ fún un. O lè fi káàdì ìkànnì wa sínú lẹ́tà náà, ìwé ìkésíni tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú
-
Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ pọ̀ jù. Tètè sọ nǹkan tó o fẹ́ sọ kó máa bàa sú ẹni tó ń kà á.—Wo àpẹẹrẹ irú lẹ́tà tá a kọ láti fi wàásù lójú ìwé 8
-
Tún un kà kó má bàa sí àṣìkọ kankan níbẹ̀, jẹ́ kó rọrùn ún kà. Ríi dájú pé o kọ ọ́ bíi pé ọ̀rẹ́ rẹ lò ń kọ ọ́ sí, fọgbọ́n kọ ọ́, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tuni lára. Fi sítáǹbù sí i dáadáa.