Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 KỌ́RÍŃTÌ 1-3

Ṣé Ẹni Tara Ni Ẹ́ Tàbí Ẹni Tẹ̀mí?

Ṣé Ẹni Tara Ni Ẹ́ Tàbí Ẹni Tẹ̀mí?

2:14-16

Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló yẹ kó máa sapá láti di ẹni tẹ̀mí, kó sì máa tẹ̀ síwájú. (Ef 4:23, 24) Kó o tó lè máa tẹ̀ síwájú, o gbọ́dọ̀ máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé, kó o ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí, kó o sì máa fi àwọn èso tẹ̀mí ṣèwà hù.

Báwo ni ipò tẹ̀mí rẹ ṣe rí báyìí tó o bá fi wéra pẹ̀lú bó ṣe rí lọ́dún tó kọjá, ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tàbí nígbà tó o ṣèrìbọmi?