Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ohun téèyàn fojú rí máa ń gba àfíyèsí ẹni gan-an, ó máa ń ranni lọ́wọ́ láti lóye ohun tó ń kọ́, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn rántí. Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá wa máa ń lo ohun téèyàn lè fojú rí láti kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Jẹ 15:5; Jer 18:1-6) Jésù Olùkọ́ Ńlá wa náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Mt 18:2-6; 22:19-21) Ọ̀kan lára ohun téèyàn lè fojú rí ni fídíò, ó sì ti wúlò gan-an láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ṣé o máa ń lo fídíò dáadáa tó o bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

A ti ṣe àwọn fídíò mẹ́wàá tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínu ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò yẹn wà fún àwọn ìbéèrè kan nínú ìwé náà. Tá a bá ń lo ìwé yìí lórí ẹ̀rọ, a máa rí ìlujá tó máa jẹ́ ká mọ ìgbà tá a máa fi fídíò kọ̀ọ̀kan han ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Láfikún síyẹn, a tún ní àwọn fídíò míì nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa.

Ṣé ó máa ṣòro díẹ̀ fún ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti lóye ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́? Àbí ìṣòro kan wà tí ẹni náà ń dojú kọ? O lè wá àwọn fídíò tó máa ràn án lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org® àti Tẹlifíṣọ̀n JW. Ìwọ àti ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè jọ wò ó, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò rẹ̀.

Oṣooṣù ni àwọn fídíò tuntun ń jáde. Bó o ṣe ń wò wọ́n, ronú nípa bó o ṣe lè fi ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́.