Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 12-14

Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Fi Ìfẹ́ Hàn Síra Wa

Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Fi Ìfẹ́ Hàn Síra Wa

12:10, 17-21

Tẹ́nì kan bá ṣàìdáa sí wa, yàtọ̀ sí pé kò yẹ ká ṣàìdáa sẹ́ni náà pa dà, ohun tó túmọ̀ sí láti fi ìfẹ́ hàn ni pé ká ṣoore fẹ́ni yẹn pa dà. “Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu; nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò máa kó òkìtì ẹyín iná lé e ní orí.” (Ro 12:20) Oore tá a bá ṣe sẹ́ni tó ṣàìdáa sí wa tiẹ̀ lè mú kẹ́ni náà kábàámọ̀ ohun tó ṣe.

Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tẹ́ni tó o ṣẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀ fàánú hàn sí ẹ pa dà?