Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

March 16-22
  •  Orin 18 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Ísọ̀ Ta Ogún Ìbí Rẹ̀”: (10 min.)

    • Jẹ 25:27, 28​—Ìbejì ni Ísọ̀ àti Jékọ́bù, àmọ́ ìwà wọn yàtọ̀ síra (it-1 1242)

    • Jẹ 25:29, 30​—Ísọ̀ ò ronú kó tó ṣèpinnu torí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, ebi sì ń pa á

    • Jẹ 25:31-34​—Aláìmoore ni Ísọ̀, ó fi ìwàǹwára ta ogún ìbí rẹ̀ fún Jékọ́bù nítorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré (w19.02 16 ¶11; it-1 835)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)

    • Jẹ 25:31-34​—Kí nìdí tí a ò fi lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn baba ńlá Mèsáyà gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́bí? (Heb 12:16; w17.12 15 ¶5-7)

    • Jẹ 26:7​—Kí nìdí tí Ísákì ò fi sọ òkodoro ọ̀rọ̀ nínú ipò tó bá ara rẹ̀ yìí? (it-2 245 ¶6)

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 26:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 78

  • Máa Lo Fídíò Tó O Bá Ń Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Kọ́ni: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú? àti Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà? Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá wo fídíò kọ̀ọ̀kan tán, béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo lo ṣe lè lo fídíò yìí nígbà tó o bá ń fí ìwé Ìròyìn Ayọ̀ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́? (mwb19.03 7) Kí lo kíyè sí nínú fídíò náà tó máa wúlò fún ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Rán àwọn ara létí pé ẹ̀dà ìwé Ìròyìn Ayọ̀ tó wà lórí ẹ̀rọ̀ ní ìlujá tó máa gbé wọn lọ síbi tí fídíò kọ̀ọ̀kan wà.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 17 ¶1-8

  • Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

  • Orin 107 àti Àdúrà