Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

March 30–April 5

JẸ́NẸ́SÍSÌ 29-30

March 30–April 5
  • Orin 93 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Jékọ́bù Fẹ́ Ìyàwó”: (10 min.)

    • Jẹ 29:18-20​—Jékọ́bù gbà láti sin Lábánì fún ọdún méje kó lè fẹ́ Réṣẹ́lì (w03 10/15 29 ¶5)

    • Jẹ 29:21-26​—Lábánì tan Jékọ́bù, ó fún un ní Líà dípò Réṣẹ́lì (w07 10/1 8-9; it-2 341 ¶3)

    • Jẹ 29:27, 28​—Jékọ́bù ṣe ohun tó dáa nínú ipò tí kò rọrùn

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)

    • Jẹ 30:3​—Kí nìdí tí Réṣẹ́lì fi ka ọmọ tí Bílíhà bí fún Jékọ́bù sí ọmọ òun? (it-1 50)

    • Jẹ 30:14, 15​—Kí nìdí tí Réṣẹ́lì fi torí èso máńdírékì yááfì àǹfààní tó ní láti sùn ti ọkọ rẹ̀ kó lè lóyún? (w04 1/15 28 ¶7)

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 30:1-21 (th ẹ̀kọ́ 2)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 57

  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Wàásù fún Àwọn Afọ́jú”: (10 min.) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó apá yìí. Bi àwọn ará ní ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fí ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn afọ́jú lọ́wọ́? Ibo la ti lè rí àwọn afọ́jú? Báwo la ṣe lè bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn? Àwọn nǹkan wo ni ètò Ọlọ́run ti pèsè kí àwọn afọ́jú lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

  • Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe: (5 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù March.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 17 ¶13-17

  • Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

  • Orin 30 àti Àdúrà