Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 29-30

Jékọ́bù Fẹ́ Ìyàwó

Jékọ́bù Fẹ́ Ìyàwó

29:18-28

Jékọ́bù ò mọ̀ pé òun máa kojú ìṣòro nínú ìgbéyàwó òun. Réṣẹ́lì àti Líà di orogún. (Jẹ 29:32; 30:​1, 8) Láìka èyí sí, Jékọ́bù rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. (Jẹ 30:​29, 30, 43) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.​—Rut 4:11.

Lónìí, àwọn tó bá yàn láti ṣègbéyàwó máa kojú ìṣòro. (1Kọ 7:28) Síbẹ̀, tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tí wọ́n sì ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ, ìgbéyàwó wọn á dùn bí oyin.​—Owe 3:5, 6; Ef 5:33.