Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

March 9-15
  • Orin 132 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́​—Fídíò: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló fi hàn pé akéde náà lo ìbéèrè lọ́nà tó tọ́? Báwo ni akéde náà ṣe fèsì nígbà tí onílé dáhùn lọ́nà tí kò tọ́ nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́?

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. (th ẹ̀kọ́ 1)

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 12)

  • Ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé fìfẹ́ hàn. Ṣe bíi pé ẹ wo fídíò Ìrántí Ikú Jésù kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀ (àmọ́ ẹ má ṣe wò ó). (th ẹ̀kọ́ 11)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 25

  • A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pe Àwọn Èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi ní Saturday, March 14: (8 min.) Ìjíròrò. Fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ìwé ìkésíni náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a máa lò. Sọ ètò tí ìjọ ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.

  • Àwọn Wo Ni Mo Lè Pè?”: (7 min.) Ìjíròrò.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 16 ¶16-19

  • Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

  • Orin 9 àti Àdúrà