MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àwọn Wo Ni Mo Lè Pè?
Lọ́dọọdún, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pe àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá à ń pè la ò mọ̀ rí. Àmọ́ ó tún yẹ ká gbìyànjú láti pe àwọn tá a mọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti wá tó bá jẹ́ pé ẹni tí wọ́n mọ̀ ló fún wọn ní ìwé ìkésíni. (km 2/09 1 ¶3; w13 1/15 32) Àwọn wo la lè pè wá?
-
Àwọn mọ̀lẹ́bí wa
-
Àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ ilé ìwé wa
-
Àwọn aládùúgbò wa
-
Àwọn ìpadàbẹ̀wò àtàwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, yálà èyí tá à ń ṣe lọ́wọ́ tàbí èyí tá a ti pa tì
Bákan náà, àwọn alàgbà máa pe àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Kí lo lè ṣe tí ẹni tó o fẹ́ pè ò bá gbé ládùúgbò yín? O lè wá àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi níbi tẹ́ni náà ń gbé. Wàá rí i lórí ìkànnì jw.org/yo, ní abala tá a pè ní NÍPA WA, lọ sábẹ́ “Ìrántí.” Bó o ṣe ń múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, ronú nípa àwọn tó o lè pè kó o sì gbìyànjú láti fún wọn ní ìwé ìkésíni.