Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
●○○ NÍGBÀ ÀKỌ́KỌ́
○●○ ÌPADÀBẸ̀WÒ ÀKỌ́KỌ́
Ìbéèrè: Kí nìdí tí Jésù fi kú?
Bíbélì: Mt 20:28
Ìbéèrè fún ìgbà míì: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe kú fún wa?
○○● ÌPADÀBẸ̀WÒ KEJÌ
Ìbéèrè: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì bí Jésù ṣe kú fún wa?
Bíbélì: Jo 17:3
Ìbéèrè fún ìgbà míì: Kí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láwọn ìpàdé wa?
ÌKÉSÍNI SÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI (March 14–April 7):
O lè sọ pé: “A fẹ́ pè yín síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ṣe ìpàdé pàtàkì yìí kárí ayé.” Fún ẹni náà ní ìwé ìkésíni, kó o wá sọ pé: “Ìwé ìkésíni yìí máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ibi tá a ti fẹ́ ṣe é ládùúgbò wa àti àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀. A tún fẹ́ kẹ́ ẹ wá gbọ́ àkànṣe àsọyé kan ní ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi náà.”
Tí Ẹni Náà Bá Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀ Rẹ, Fi Ìbéèrè Yìí Sílẹ̀: Kí nìdí tí Jésù fi kú?